Aráàlú fi ìlú sílẹ̀ ní Kwara lẹ́yìn tí àwọn agbébọn kọ lẹ́tà pé àwọn ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkan awọn eeyan ilu Ira ni ijọba ibilẹ Ọyun ,ipinlẹ Kwara o balẹ mọ latari iwe tawọn agbesunmọmi kọ si ilu naa laipẹ yii.
BBC Yorùbá kan si ilu naa lonii ọjọ Aje lati wo bi nnkan ṣe ri nbẹ, niṣe lawọn kan tibẹrẹ si n fi ilu naa silẹ.
Gbogbo ilu naa lo pa lọ lọ ti ibẹru si gba ọkan awọn eeyan ilu ti wọn o mọ igba tawọn agbesunmọmi le kọlu wọn.
Kini ohun ti awọn ara ilu sọ?
Lasiko to n ba akọroyin BBC Yorùbá sọrọ laarọ oni, ọkan lara awọn agba ilu naa, Alhaja Rashidat Iṣọla sọ pe, awọn o loju orun mọ lati bi ọjọ mẹta sẹyin ti awọn agbebọn ti kọwe si ilu naa.
O ni garaji awọn ọlọkada ni wọn ti ri iwe naa ti wọn si mu iwe naa lọ sọdọ Kabiesi.
Ninu ọrọ rẹ, Abdulganiyu Aliu to jẹ awakọ kẹkẹ Maruwa sọ pe, awọn ọmọ awọn o le lọ ile ẹkọ lati ọsẹ to kọja ti wọn ti ri lẹta naa.
O ni gbogbo ara ilu ni ọkan wọn o balẹ, koda, awọn eeyan o le wa si ọja mọ, awọn eeyan perete to wa laarọ yii ti palẹmọ ki aago mẹwa owurọ to lu.
O fi kun pe, awọn gbọ pe awọn agbebọn tun kọlu oko kan ni ilu Ilẹmọna laarọ oni.
O fi kun pe awọn eeyan ti n fi ilu naa silẹ bayii lọ si ilu mii, paapaa awọn akẹẹkọ ti wọn n gbe ninu ilu naa lati wa kawe, bẹẹ ni awọn to ni arugbo ninu wọn ti n gbe arugbo wọn kuro laarin ilu.
Awakọ naa wa parọwa si ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Kwara lati ba wọn ko ẹṣọ alaabo wa si ilu naa ki ọkan wọn le balẹ.
Aṣoju kọroyin wa kan si awọn ile ẹkọ meji ni ilu ọhun, Muslim Primary school ati Ira Grammar School Ira, ṣe ni gbogbo ẹ da paro paro latari bawọn akẹẹkọ ati olukọ ṣe fìdi mọ le.
Ọgbẹni Saliu Olawale sọ pe, bi gbogbo nnkan ṣẹri bayii ti domi tutu sọkan awọn eeyan ilu naa pẹlu bi kaluku ṣe n gbe ninu ibẹru.
Àwọn agbésùnmọ̀mí kọ lẹ́tà sí ìlú mẹ̀ta ní Kwara pé àwọn ń bọ̀
Ibẹrubojo ti gba ọkan awọn eyan ijọba ibilẹ Oyun, nipinlẹ Kwara latari bi awọn agbesunmọmi ṣe kọwe si ilu mẹta ọtọtọ ni ijọba ibilẹ naa.
Awọn ara ilu mẹtẹta naa ni ọkan wọn o balẹ mọ bayii ti wọn si n ronu ọna ti wọn le gbe gba.
Niṣe lawọn eeyan ilu mẹtẹta ṣadede ji laarọ kutu ti wọn si ri ri iwe kan tawọnagbsunmọmi naa kọ si wọn lọjọ kejil, oṣu Keji, ọdun 2025 yii.
Awọn ilu mẹta ti wọn kọ iwe ọhun si ni ilu Ira, Inaja ati Hahọ.
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iṣẹlẹ naa, ọkan lara awọn ọmọ ilu Ira, arabinrin Fatima Salau sọ pe aarọ kutu ni awọn ri iwe naa.
O fi kun pe awọn ọlọkada lori iwe ọhun nibudo wọn ti wọn si mu lọ fun awọn agbagba ilu.
O ṣalaye pe awọn ko ri iru iwe bẹẹ ri ni ilu awọn ati pe igba akọkọ ree tawọn yoo ri iru iwe bẹẹ.
Lati igba ti wọn ti gba lẹta ọhun lawọn eleto aabo ti yi ilu naa ka fun aabo to peye.
Araalu naa sọ siwaju si pe awọn alaṣẹ ilu ti fofin de ipade adura oru lawọn ile ijọsin ati mọṣalaṣi.
Ki lo wa ninu iwe ti agbesunmọmi kọ?
Ohun tawọn agbesunmọmi naa kọ sinu iwe naa ni pe "awa ẹgbẹ agbesunmomi ilẹ Naijiria, Nigeria Terorist Association n bọ wa kọlu Ilu Ira, Inaja ati Hahọ.
"Kosi ilu kankan to ba wa lẹru lati kọlu.
"A maa n ṣe iwadi wa daadaa, a si ma n fi imu finlẹ ka to sakọlu.
"A tigbọ nipa ilu yii, ilu Ira, a si mọ pe ẹ ni awọn alagbara to le koju awọn ọmọ ogun wa.
"Ẹ gbaradi fun wa ni igbakugba, ko i ohun to kan wa pẹlu gbogbo Ifia ati awọn alagbara ti ẹ ni."
Lẹta ọhun sọ siwaju si pe awọn ti kuro ni Kaiama, awọn si n bọ wa si ilu Ira, Inaja, Hahọ ati agbegbe rẹ.

Igbesẹ wo ni ijọba n gbe?
Alaga ijọba ibilẹ Ọyun, Alhaji Kamoruden Akanbi ti pe ipade igbimọ eleto aabo ijọba ibilẹ naa.
Ipade naa waye ni olu ile iṣẹ ijọba ibilẹ Ọyun ni Ilu Ilẹmọna.
Alaga naa ni wọn ti fi ọrọ naa to oun leti iṣẹ si ti bẹrẹ lori ẹ.
O ṣalaye pe ijọba ibilẹ Ọyun fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ Kwara lati koju eto aabo to mẹhẹ.
Alaga ọhun wa ke si ara ilu lati maa kiyesi ara ni gbogbo igba ki wọn si ma funra si awọn ajoji eyan ti wọn bari lagbegbe wọn.



























